Stats: 3,232,329 members, 8,091,061 topics. Date: Saturday, 01 March 2025 at 10:59 AM |
Nairaland Forum / Nairaland / General / Religion / Cac Hymns For Morning Devotion (582 Views)
Jehovah Allah: Lagos Temple Where Worshippers Sing Hymns, Recite Quran / Download Audio: Morning Devotion Worship Songs By Nathaniel Bassey And Sinach / Stories Behind Great Hymns.... .pass Me Not, O Gentle Savior (2) (3) (4)
Cac Hymns For Morning Devotion by fashdesigncoach(f): 6:16am On Mar 06, 2022 |
These hymns really bring back some good memories. I was blessed to be born into a CAC family where every single day, the bell (agogo igbala) would ring and we all MUST ASSEMBLE to the living room where Bibles and HYMNBOOKS were neatly stacked on the shelves. my Father made sure everyone of the family had at least a Bible and a hymnbook... these hymns where a major part of the family devotion. We would sing from the hymnbook with a LOUD VOICE. yes...IT WAS IMPORTANT... VERY IMPORTANT All these hymns became part of me and my siblings while growing up...and it's impact is still with us till today. Proverbs 22:6 says 'Train up a child in the way he should go: and when he is old, he will not depart from it.' Thank you Dad and mum (keep resting in the Lord...I miss you) for the priceless gift of training us in the way of the Lord. https://www.youtube.com/watch?v=i1kFTKmqfN4 CAC HYMNS FOR MORNING DEVOTION. IMOLE OORO DIDUN YI WASODO MI OLUWA MI OLUWA MI MO UN JADE LO |
Re: Cac Hymns For Morning Devotion by fashdesigncoach(f): 6:17am On Mar 06, 2022 |
IMOLE ORO DIDUN YI Verse 1 Imole oro didun yi Ji mi nin'orun mi Baba, ife Tire nikan L'o pa omo Re mo Verse 2 Ni gbogbo oni, mo be o Ma se Oluso mi Dariji mi, Jesu mimo Ki'n je Tire loni Verse 3 Wa se 'bugbe Re ninu mi Emi ore-ofe! So mi di mimo laye yi K'emi le r'oju Re |
Re: Cac Hymns For Morning Devotion by fashdesigncoach(f): 6:18am On Mar 06, 2022 |
BABA MI GBO TEMI Verse 1 BABA mi gbo temi 'Wo ni Alabo mi, Ma sunmo mi titi; Oninure julo! Verse 2 Jesu Oluwa mi, Iye at'ogo mi, K'igba naa yara de, Ti n o de odo Re. Verse 3 Olutunu julo, 'Wo ti n gbe inu mi, 'Wo to mo aini mi, Fa mi, k'o si gba mi. Verse 4 Mimo, mimo, mimo, Ma fi mi sile lai, Se mi n'ibugbe Re, Tire nikan lailai. |
Re: Cac Hymns For Morning Devotion by fashdesigncoach(f): 6:20am On Mar 06, 2022 |
WA S'ODO MI, OLUWA MI Verse 1 WA s'odo mi, Oluwa mi, Ni kutukutu owuro; Mu kero rere so jade, Lat'inu mi soke orun. Verse 2 Wa s'odo mi, Oluwa mi, Ni wakati osan gangan; Ki'yonu ma ba se mi mo, Won a si s'osan mi d'oru. Verse 3 Wa s'odo mi, Oluwa mi, Nigba ti ale ba n lẹ lo; Bi okan mi ba n sako lo, Mu pada; f'oju 're wo mi. Verse 4 Wa s'odo mi, Oluwa mi Ni oru, nigba ti orun, Ko woju mi; je k'okan mi Ri sinmi je ni aya Re. Verse 5 Wa s'odo mi, Oluwa mi, Ni gbogbo ojo aye mi; Nigba ti emi mi ba pin, Ki n le n'ibugbe lodo Re. |
Re: Cac Hymns For Morning Devotion by fashdesigncoach(f): 6:22am On Mar 06, 2022 |
OLUWA mi, mo n jade lọ - Forth in Thy Name, O Lord, I go OLUWA mi, mo n jade lọ, Lati se isẹ ojọ mi, Iwọ nikan l'emi o mọ, L'ọrọ, l'ero, ati n'ise. Isẹ t'o yan mi l'anu RẸ, Jẹ ki n le se tayọtayọ; Ki n roju Rẹ ni isẹ mi, K'emi si le f'ifẹ Rẹ han. Dabobo mi lọwọ 'danwo, K'o pa ọkan mi mọ kuro, L'ọwọ aniyan aye yi, Ati gbogbo ifẹkufẹ. Iwọ t'oju Rẹ r'ọkan mi, Ma wa lọw' ọtun mi titi; Ki n ma sisẹ lọ lasẹ Rẹ, Ki n f'isẹ mi gbogbo fun Ọ. Jẹ ki n r'ẹru Rẹ t'o fuyẹ, Ki n ma sọra nigba gbogbo; Ki n ma f'oju si nkan t'ọrun, Ki n si mura d'ọjọ ogo. Ohunkohun t'o fi fun mi, Jẹ ki n le lo fun ogo Rẹ; Ki n f'ayọ sure ije mi, Ki n ba Ọ rin titi d'ọrun. AMIN |
(1) (Reply)
Pastor Asked A Female Minister To Sleep With A Barrened Woman For Her To Conceiv / Mami Wata: The Scared Female African Water Goddess / Theobart Grant, Legit Or Scam?
(Go Up)
Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10) Nairaland - Copyright © 2005 - 2025 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 21 |