Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,218,607 members, 8,038,542 topics. Date: Friday, 27 December 2024 at 07:19 PM

Oriki Oyan Town In Osun State, Nigeria - Nairaland / General - Nairaland

Nairaland Forum / Nairaland / General / Oriki Oyan Town In Osun State, Nigeria (591 Views)

History And Oriki Of Inisa, Osun State / History Of Oba-ile Town In Osun State / Ado-Awaye: The 7 Wonders Of The Mysterious Town In Oyo (2) (3) (4)

(1) (Reply)

Oriki Oyan Town In Osun State, Nigeria by Jimsonjaat86: 10:54pm On Dec 11, 2023
Ọmọ Ọba Oyan, mo finran mojare
Mo jare Oro wanti loye
Omo ero jewo tita mo ta tan
Bi won o wi, won a ni sisan losan
Sisan losan iyeru lode ogbogi
Ogbogi to suna kankan
Ogboniyan a pitan Oro loye
Ogbo bole ni t'Owu
Arinrin Ile baba to biwa ni taso
Ajuba ni Ile oka

Pepepe ni aso awon t'Otan
Elegodo ni aso awon Ijesa
Eyi toyemi loja ni e ra mi wale
Ki n ri Jo sesengudu Oloye
Won lu koso, Ori mi Jo
Won lu agere, nko pase da
Igbati won lu yeyeruba ni mo ba fo sijo
Won bani ki n mo JoJo Oloye kalo
Won kii Jo Oloye dunmi
Won kii Jo Oloye dunran baba mi

Oloyan, omo egberun agbe
Oloyan omo egberun aluko
Atagbe ataluko ni be ni igberi egun
Nibi tomi ti n sun sayaba lenu
Oloyan, omo o wo sowoye
Omo a fosan gori egun
Omo akutan fori egun Sona
Omo akutan fori egun seye
Ajooji ki bawa dedi egun
Ajooji to ba bawa dedi egun, edan ni won fi n yoju won

Omo ladelade mi o niye ninu Ile oba
Omo eri nimi, n o gbudo mu
Ejeu no mi, n o gbudo bu wese
Telegun ni mi, n o gbudo ja lemo lowo sere
Sebi, Kekere Oyan, akin ni
Agba Oyan, awon lomoran
Eniyan Oni gbe ilu Oyan komo gbon denu
Ogbon ni n be lodokun Baba tiwọn

(1) (Reply)

Which Country Is Stronger Iran Or Israel, Militarily And Economically? / WELCOME ON BOARD!!! / Intro

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 5
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.