Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,193,738 members, 7,952,011 topics. Date: Wednesday, 18 September 2024 at 09:22 AM

Hammao's Posts

Nairaland Forum / Hammao's Profile / Hammao's Posts

(1) (of 1 pages)

Culture / Re: Yoruba Peeps, Kini Oriki Ilu Re? by hammao: 12:03pm On Jun 23, 2012
ORIKI OFFA

Ede Okin Olofa Mojo,
Olofa, omo Ola nlo.
Olalomi, abisu joko, Ijakadi katakiti l’oro Offa.
Ija peki abe Owula, ti ko ba se oju ebe ni aala.
A se oju poro ninu oko.
Kiba se oju Oloko, Oloko o ba lawon.
O s’oju agunmate, O’soju agbele ya arara, O s’oju apobiirii kako.
Kini se kagun kakan orun nile Oba
Oka baaba, ni se kagun kakan orun! Ni Offa, Agbado ni agun mate,
Eree ni agbe le ya arara, Isu ni apobiiri ka inu oko.
Omo Odi meta ara tinbe ni Offa; Odi iwaju ni ti Olusan, Odi tehin nit i Olumorin,
Odi ti aarin gbungbun ni ti Olugbense, omo Ayejin.
Omo Odo meta araa tin be ni Offa.
Okan ni ki won o pa Erinla bo ohun ki ohu di Odo Okun.
Ekeji ni ki won o pa Agbo bolojo bo ohun ki ohun di Odo Osa.
Eketa ni ki won o pa Akuko Adie gagara bo ohun ki ohun di Agunloko ni Offa
Oba ni okokan ilu tito ra Agbo bolojo,
Onini gbogbo ilu tito ra Erinla.
Sugbon tikan bad i Odo Okun, ti ekeji di Odo Osa,
Nibo ki ako gbogbo omo beeree wonyi si.
Eyi toni ki won pa Akuko adie gagara lo di Agunloko ni Offa
Ti gbogbo wa npon mu.
Olofa laare ki Offa okun te te.
Olofa laare ki odogba, okan Ogbodo jukan.
Ti okan bu okan, ti okan , ti okan ba ju’kan
Oba ni ko won r’oro.
Oba o ko wa t’awa d’oro o’diran baba wa.

Peki mo ba Odofin d’imuu, mo se Ojomu kanrin kese,
Mo fi ehin Saawo balee l’oja Offa.
Offa o mo Akaa, Ijakadi l’oro wa.
Olofa laaree,
Offa o mo Akaa, nibi ti eegun eru ti mule ti oju ti omo bibi lo.
Omo okuta meta ara, mo ko ese lara akoko,
Ekeji nse mi pele, Eketa ni kin ma rora.
Akoko ni, Nigbati mi o mo ona kini mowa de ilu ete.
Ekeji ni, Nigbati mi o mo ona kini mowa de ilu ote..
Eketa ni, Nigbati mi o mo ona kini mowa de ilu owon won.
N’ile Olalomi, nibiti Omi ti won to ju Oti lo.
Ede Okin, ti mo ri Ookin bu mu, Mo fi Abata fo ese.
Ni Offa ti mo ri Abelenje bu bo oju.
Laare ki Offa okun te te.
Bata dun pantan-pantan, ohun ki mi ohun la mi.
Olalomi, tani ko sehun ninu won.
Ile yi ogba wa a lo si lloffa.
Nigbati lloffa o tun gba wa mo a lo si Offa Oro.
Offa Oro o gba wa a lo si Offa Rese.
Nigbati Offa Irese tun kere ju, a pada si Offa Eesun.
Offa Eesun ko bat un gba wa mo a ko lo si Offa Arinlolu.
Olofa se pele o!
Aro o ya bu mu, beeni ko ya bu boju.
Igunungun ni mo ri ti mo da asa j’edo.
Akala ni mo ri ti mo da asa geruu.
Olofa, Imole ni mo ri ti mo da asa la mi ni abee.
Olofa lo ni Omoo.
Kos i Omo to ju ti Olofa bi ko se Oyo.
Olofa loni Omo, gbengbenleku ni arayoku nsan.
Beni won ki Olalomi Iyeru-Okin, Olofa mojo.

ORIKI ANOMO
Kukunduku de abewe geru-geru.
Obo Omo bo Iya.
Obo Baba, bo Omo.
Obo Oko bo iyawo e.
Adun wo labe Oori.
Ajunilo tinfi owo ola ran i lori.
Pekelola, ara idi Egungun.
Pekelola, amuyan ni igun.
Eniti Olofa otete ri ti obi Ifa re leree.
Oni: A bi Pekelola nba mi ja lawo ara ni?
Pekelola, amuyan ni igun.
Kos i nile Iyan okun odo.
Pekelola de, Iyan kun inu odo fo-fo-fo.
Ore Olofa.
Awo Ojomu.
Imule Saawo.
Eniti Olofa kotete fi ote lo.
Ti Ilu fee tu.
Won so fun Pekelola tan,
Iyan yi piriipi ninu Odo.
Pekelola, de, de, ki aye o’yemi t’omo’tomo.
smiley smiley smiley smiley smiley smiley smiley smiley smiley smiley smiley smiley smiley smiley smiley smiley

5 Likes

Educational Services / Re: GRE And TOEFL Examinations by hammao: 9:27am On Mar 14, 2008
oga consultant, i intend to write GRE and TOEFL by may please i will need your coaching please. where is the best center to register,  embarassed

(1) (of 1 pages)

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 11
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.