Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,187,456 members, 7,932,512 topics. Date: Tuesday, 27 August 2024 at 08:17 AM

Marv006's Posts

Nairaland Forum / Marv006's Profile / Marv006's Posts

(1) (of 1 pages)

Culture / Re: .. by marv006: 12:04am On Apr 28, 2016
IFA ISEGUN.
Ewe Ifa: ewe awede(make sure it is the real deal), ewe jiiwini, apere ajadi, ati aso funfun.

Ao gun awon ewe na po, ao fi ose ti a le lo lekan soso koo.
Ao mu apere ajadi losi odo to nson, ao ji lo ni owuro laifohun,
ao fi apere na si arin odo, ao da oju ko ibi to ti nson wa,
ao ko si inu apere na, ao we ose naa,
ao gbudo wo eyin titi ti ofi dele, ao gbudo fo ohun si eni kankan bakan na.
Note: ti a ba n we lowo, ao ma se awure:
awede werisa wemi mo, we mi fun owo,awede werisa wemi mo, wemi fun aya rere/oko rere,
awede werisa we mi mo, wemi fun omo rere.
Ao fi aso(cloth) ta'wo lo si odo, s'eba odo naa, ao ni fi owo(hand) wa kan mo oo,
ao wo aso funfun ti amulo si odo wa si ile, yio wa larawa fun ojo yen. Leyin na egbinyanju kie fi ekuru ati ori se sara si agbede/orita ni ale.


EYI NI A NFI GBA KADARA(DESTINY) WA KURO LOWO AJIRAWO LO...

Adonri ponpon ti iru re gbo dada, funfun ti nbe ninu Eso Oju musu, epo obo, egbo itu, eru alamo,atare,Owu ati epo pupa.............

1 Like

Culture / Re: .. by marv006: 10:45pm On Apr 27, 2016
Aji tutu gb'aye
Arin ginniginni gb'ayi
Ojini kutu kutu rohun oro sarigbon lo' orun,
Adi'fun Orunmila, baba n'torun bowaye,
Dia fun omo eniyan, won maa pin si ero meta la'ye,
Awon ti won wa sa'ye,
Awon ti won sin won wa sa'ye,
Awon ti won wa wo'ran la'ye,
Won bo wa hu'wa ire,
Won bo wa hu'wa ibi,
Won bo wa se kose'bi-kose're,
Asee moga-moga kii ri ohun oro se argbon lo o,
Awo agbonniregun, dia fun agbonniregun,
Onti'kole aye losi ikole orun,
Oun lo sodo Eledumare lo beere oro,
Eetiri ti Olodumare fida ero meta,
Ati oun meta si ile aye leekanso,
Oni aki ida akoni meta si ile aye kiwon o ma fi apa gun arawon,
Nitoripe bi iga ba'gba iga, okan ate.....Ogbe Ofun lo so bee.



AWURE ORI.

Kanrangbo l'awo karangbon,
Jaguda l'awo jaguda,
Erin akoki ni salaabarin omo eranko,
Adia fun orunmila, baba nlo se onike ori laye,
Nje ti aba burin gada,
Bi aba ni owo kan asiko,
Bi aba burin gada,
Bi aba ni aya rere ni asiko,
Bi aba burin gada,
Bi aba bimo rere ni siko,
Bi aba burin gada ni ire gbogbo ni asiko,
Bi aba ji, a ni Ifa o seun,
Ifa aani; oun ko, Ori ni,Ori lo seyun-un.
Nje Ori mi gbemi, ori mi la mi,
Gbemi atete niran,
Atete gbeni ku' f'Oosa,
Ori ni ngbeni ki se'Oosa
Ori a gbe wa si ire gbogbo oo
Culture / Re: .. by marv006: 10:42pm On Apr 27, 2016
FUN AWON TI WON MU ABUBO/ AJEEGUN..

Ao lo owo ati ese Oga mereerin ni otooto,
Ao lo eeyin(front tooth) oke- eeyin iwaju Elegede eyokan,
ao pin si ona meerin bakan naa,
Ao wa lo mariwo ope na si papo,
Ao fi sin gbere si orun owo wa mejeji ati ese wa mejeeji,
Ao sin owo oga otun si owo(hand) wa otun, ao sin owo(left hand) oga si orun owo osi wa, bee lao se ese mejeeji naa.

Hnmm beni, yio je fun wao..
Nitoriwipe anamu ni ti Oga
Ara ni ti Elegede
Eeyo ni ti moriwo..bi mariwo ope ba yo, akoju si Olodumare ni.
Eyi mo ba wi ni Ifa o se.

1 Like

Culture / Re: .. by marv006: 10:19pm On Apr 27, 2016
Ifankaleluya:


Okare Babalawo

O si mu mi ranti Owonrin Olola(owonrin-were), Ki ebo fin oooooo.

Ifa ni;

Bi asinwin(re mi mi)

Bi asinwin

Bi were(do do) bi were

Bi were

Adifa fun Labalaba ti o faye so fe je,

Won ni o sakele ebo ni o se,

O gbebo nibe o si sebo

O geru atukan esu o si tu

O gbo kara ebo nibe o si ha

Igbayi lawon omo-kekere nle labalaba kiri,

labalaba o fo soke yio wipe

Bi asinwin bi asinwin,

Labalaba o tun fo wale

Yio wipe bi were-were

Bayi ni o gbe awon omode wo inu gbo lo...

Labalaba wa n faye sofe je.....

Orunmila erigi-alo ifa jia faye so fe je....!

O si mu mi ranti Isegun ota oni Owonrin-were to je wipe bi Babalawo, Onisegun, Alfa, Woli, ati whatever ba sa si eeyan. Iro ni won fi pa...!

Aboru Aboye!

Nje iba akoda iba aseda, gbo gbo omo awo ni ko ma juba won,
Nje iba ni ti oniba, omo awo ti ko ba juba akoda, ifa re ko nise,
awo ti koba juba aseda, ebo re ko ni'da,
nje iba ni ti oniba, emi juba akoda ati aseda.....
Iba re o Agba-Awo to gbo'fa gaara... Ifankaleluya iba o.
Nje iba gbogbo awo to wa lori eto yio,botilewu ki awo o kere to,
aki ifi oju di awo, iba gbo gbo ile o..Aboru Aboye.

2 Likes

Culture / Re: .. by marv006: 12:12am On Apr 17, 2016
Atupuru odo ni kose fi gunyan,
Atupuru ikoko ni won fa lokun danyin-danyin-danyin,
A dia fun Ori,
Ori wa nlo ode Ajalaye,
won ni ko sakaale ebo ni sise,
Ogbebo orubo,
Nje Awede we tie o mo,
Ella ifa, we Ori mi mo,
Ogede we tie o de,
Ella ifa wa weri mi mo,
Ara kii ni ogede koma de,
Ella ifa wa weri mi mo,
Ero woo ni ti igbin,
Ella ifa wa weri mi mo.

Ise keke kan nu fun awon ti ooye ye.
Culture / Re: .. by marv006: 11:58pm On Apr 16, 2016
OWONRI IWORI

Ise ni o se gunnugun ko ba loorun,
A dia fun Owonrin omo asegilowo,
Osi nio takala ko ba leruwa,
A dia fun Iwori omo atapola sola,
awon iwo o sai la, emi o sai la,
A dia fun Alafohunfojuri omo asoru ta ra igba eru,
awon le la laye bi?
ebo ni won ni won o ru o,
igba ti won rubo ni ise ba tan, loro ba de,
nje iwo o sai la, emi o sai la,
gbogbowa la o la si rere laye o.
Culture / Re: .. by marv006: 11:40pm On Apr 16, 2016
PAPA LO JO MO LO TANHUN TANHUN,
OGUNNA KAN SOSOOSO LO SO ELULU DILEELE,
A DIA FUN ANRERE OMO OLODUMARE,
OMO ATENI LEGELEGE FORI SAGBEJI OMI,
NIJO ON NI O RUBO SAIKU ARARE..

.....Ifa losobe..OFUNOBARA.
Culture / Re: .. by marv006: 4:51pm On Apr 15, 2016
ASINA KEKE KAN NI O

ORI OKETE
EGBO TUDE
ERU ALAMO
EWE EJINRIN ATI
EWE EWURO.

ao jo, aolo, aoteni OTURA-OGBE.
ao fi eje eyele po, ao su si ona meta,
aofi REGAL lofunjo meta.
Culture / Re: .. by marv006: 1:18am On Apr 15, 2016
Atanpako ku re lese,
gbogbo ara ojo rin pee,
bi ababa pe oku ni popo,
alaye ni n daun,
adi'fun Jewesun
ti nse akanbi Eledumare agotun,
olomo ateni ola, legele f'ori sagbeji,
nigbati onbe nigbatemu omoaraye,
ebo ni won nio se,
ero po, ero ofa...
........

......Ifa loso be.
Culture / Re: .. by marv006: 11:56pm On Apr 14, 2016
IFA NLA KAN RE O( OSO)

EWE IFA: eran ifaa(okete) aaye, ewe akiriboto, aso waji, aso odo egungun pupa, egun erin, egun efon, eku eda, eja aro, ikoride, iye agbe, iye aluko, epo ose, epo odan , igi asorin, imi ojo, ataare ati .......,

IFA: Osemi so mo te idaro bo enu, emi kowaye to poburukoso(3x)
aye awagbo, aye awato, ayeawa se oun re re le oun rere ni ile aye ti mo wa. Won bi mi kini mo ndu, moni igbe aye rere ni mo ndu ti mo du titi wo gbaja ola, won bimi ni gbaja ola pe kini mo nwa, moni mofela, mofe lowo pupo, mofe bimo laye, mofe kole monle, mofese gbogbo oun rere ti egbe mi nse, won bimi se moti tee, moni moti tee, won bimi nigbati ti mo te tori kini mose tee, moni tori awon iyami osoronga, won bi mi pe nibo ni mo ti tee, moni mote ni tese lakokote kato te oju opon, moni mote ni gbaja ola, moni mo te loja iyee, moni mote niso adie, moni mo te ni wonran nibi ojumo ti ntimo wasaye, moni mo te ni oke igeti nile agbonmiregun, moni mote ni owo ire, moni mote ni sonso ori ako. Wontunbimi pe awon tani olugbenide ati olutunisile, moni eleda ni olugbenide ati olutunisile, won tun bimi pe awon tani olugbenide ati olutunisile, moni awon aje iya mi osoronga ni olugbenide ati olutunisile, wontun bimi pe tani eni dudu ati eni pupa, moni emi ko mo eni dudu ati eni pupa o, woni awon eni dudu ati eni pupa ni awon ajana jo omo, tiwon ma n fi owo won aluse fitilekun ola mo omo eniyan, eyi to jepe won yio fi owo won se kokoro fi silekun ola temi funmi ni kiakia, nigbana ni won ni ki nma lo si KARAKATADINLOGUN, nigbati mode be mo ba awon enia DUDU BI ASO WAJI, MO BA AWON PUPA RORO BI ODODO ASO EGUN,MOBA AWON ASOMU SOMU TI NMO SO OWO(HAND) OMO ARAYE MO IGI, MOBA AWON OSOYO SOO, AWON TI WON MA NJE ERAN LENU MAKUNA, MOBA AWON ADURO SEGE LORI ODO IGUNYAN FUN ORO, MOBA AWON SOKO DOMO, MOBA AWON SOKO DEJE, KANAKANA SOJU WASO WASO, gbogbo won tun bi mi pe se moti tee, moni moti tee, nigba na ni woni odi dandan ki awon o ko simi lapo kinmari oun mu sowo kale aye kiri, woni kin ma losi okakan gangan, woni nibeni mati pade ola temi, ni mo ba nlo nigbati mode agbede meji ona mo ba awon IYAKAN IYAKAN, MOBA AWON IYA LOLOGBAJA TI WON JOKO REMUREMU LABE IGI OSE, mo kiwon ni iki irele fun enitobajunilo, won bimi pe kini mo nwa, moni awon gangan ni mo nwa ti mo tun wa eyonu yin ati idunu yin si ise ati oun gbogbo ti mo ba nse, woni nitorikini mose nwa eyonu ati idunu awon, moni lati ojo ti mo ti gbonju saye timoti nri eni dudu ati eni pupa eyin ko ti fi oju rere yin wo mi,.......TO BE CONTINUED..
Culture / Re: .. by marv006: 10:46pm On Apr 14, 2016
OSE-IRETE ( OSE BI IRETE SI ILE AJE)

IFA O DI ALAJUBARAKA, EMI O DI ALAJUBARAKA,
BI ABA LO JUBARAKA KIO JUBARAKA, OBI OLOTOORO,
OBI OLOTEERE, OBI ONAWOFUNMIRIN, ONAWOFUNMIRIN
LO BI AJE, AJE LO BI ENIYAN, AJE DI ORE OLOKUN,
ENIYAN DI ORE IRADA,
OSE KIO SAREGEGE LO RE MU AJE WA FUN MI NI ILE OLOKUN,
IRETE KIO SAREGEGE RE IRADA LORE MU ENIYAN WA FUNMI,
APE KIO MAJE KI IRE MI PE KIOTODE, EJINRIN KIOMAJE KI
IRE MI RIN JINA KIOTODE, BI ABA GBALEGBA'NA,
AATAN LA NKORIRE SI, IRE GBOGBO KO WA BA MI NI JEBUTU,
IRE GBOGBO KO MO DARI SODO MI.

EWE IFA: ewe ape, ewe ejinrin, yerupe atan to gba igba ese, omi okun, ose, osun pupa not osun buke o, eje eyele funfun meji; okan fun ose okan fun irete, ara ogiri yara wa ni ao pari ise yi si o. Aini di gberee nu o, ifa awon baba nlawa niyio o, eyi ti alefi okete ti nse eran ifa na gbe ebo re wa.

1 Like

Culture / Re: .. by marv006: 8:12am On Apr 14, 2016
AJEGUN AWON BABA NLA WA RE OOO

Ika arin eranko ti a npe ni eero/inaki, ati oko atare kan ni ao jo po ti ao fi sin gbere yika orun owo wa, wa si arin ika wa ti oga julo.

FUN AWON TI OGUN KI JE LARA WON

Ao gun ewe eyin olobe pelu awo inaki die mon ose ao ma fi we.

1 Like

Culture / Re: .. by marv006: 8:05am On Apr 14, 2016
OSEFU

Bi ori osunwon, ogbon inu ni keito,
Omi nbe nile olokun, okun olori omi,
Omi nbe nile olosa osa ibikeji,
Ogbon nbe ninu akoda, akoda ti nko gbogbo aye nifa,
Oro nbe ninu aseda, aseda ti nko gbogbo agba ni imoran,
Ogbon nbe ninu orunmila amayegun, odudu ti ndu ori emere
atunritikosunwon se,
A daa fun awonkomoosekomoowa ti nfi ojoojumo kegbe ori aisunwon, pe oba eleda ti se awon ni ibi,
.............................komonosekomonowa to ko ifa,
Ori re sunwon nigbeyin ni.
Culture / Re: .. by marv006: 6:47pm On Apr 13, 2016
ORUNMILA NI ODI EDUN, MONI ODI EDUN.
ORUMILA NI ODI EDUN OKAN, MONI ODI EDUN OKAN,
ONI TI EGBE ENI BA NBA LOWO TABA LOWO,
ORI ENI LAA NKEPE, ONI TI EGBE ENI BA NSE OUN RERE,
TI ABA RI OUN RERE SE ORI ENI NA LAA NKEPE,
NJE ORI MIO O, WA SE ELEGBE LEYIN MI O,
IGBA IGBA NI OROGBO NSO LOKO, IGBA NI OBI NSO LOKO,
IGBA NI ATARE NSO LOKO. AJE KO WOLE TOMIWA,
OOGUN, AISAN, AITOEGBE,IKORIRA ETC KO POORA,
TI EFUN BA WONU OSUN APOORA, KI GBOGBO WHALA MI O POORA, AAWISE NI TI IFA, AFOSE NI TI ORUNMILA,
ABA TI ALAGEMO BA DA NI ORISA OKE NGBA, KAN KAN NI
EWE INA NJO, WARA WARA NI OMODE NBO OKO ESISI,
ILE OGBA ONA OGBA NI TI ARAGBA, GBOGBO EYI MO WI, KI ARO O RO MO.
Culture / Re: .. by marv006: 6:30pm On Apr 13, 2016
ORUNMILA NI TALOTALASAN BA ROKUN,
WONI ORI NIKAN LO TALASAN BAROKUN,
AKAPO EJUESI, EDAWO OBUN KEDASOROMI.
MAPO ELERE, MONBA OTUN, BOLAJOKO,
OKINKIN TI TO MERIN FON, O NI TA LODA ORI
NIKAN TOTALASAN BAROKUN. ORI NIKAN NI NGBENI,
TI NBA LOWO LOWO, LOWO ORI NI, TI NBA FE AYA,
LOWO ORI NI, TI NBA BIMO, LOWO ORI NI,
TI NBA NIRE GBOGBO, LOWO ORI NI, ORI NI N O MA ROFUN,
ORI MIO, ORI MI ATETE NIRAN, ATETE GBENI KO OSA,
KO SI OSA TI N DANI GBE LEYIN ORI, ORI MI PELE O.
BI BABALAWO/OLOSA/ONISANGO BAKU, WAN KO ORISA RE SONU,
TI ENIYAN BAKU KOSI ENI TI WON GE ORI RE LE,
WON SINI PELU ORI NI, ORI MI PELE O, ATETE NIRAN,
ATETE GBENI KOOSA, KO SI OSA TI NGBENI LEYIN ORI.
Culture / Re: .. by marv006: 9:26pm On Apr 12, 2016
IFA NI:

BI IGI BA DA, IGI AYERI, BI ENIYAN BAKU,
AKU ENIYAN SASASA NILE, BI ENI ORI ENI BAKU,
ENI ILELE ASIDI ENI ORI ENI, ADIAFUN ARABA PATAKI,
EYI TI YIO KEYIN IGI OKO............
Culture / Re: .. by marv006: 9:15pm On Apr 12, 2016
IFA NI:

IFA NLA NLA LA FI GBAFA NLA N LA,
OGUN NLA NLA LAA FIGBA OGUN NLA,
EGBASERE LAA FI TANRAN SERE,
IGBA TA BARI SERE MO, EMI LA FI TANRAN EGBA RE,
ADIFA FUN OLOKUN NIJO ERI GBOGBO NBA SOTA,
OSE BOWO FUN OLOKUN, OLOKUN LAGBA OMI,
ERI GBOGBO EBOWO FUN OLOKUN,
OLOKUN LAGBA OMI.

1 Like

Culture / Re: .. by marv006: 8:49pm On Apr 12, 2016
Not real
Culture / Re: .. by marv006: 8:06pm On Apr 12, 2016
OBARA IKA

Kowe awo aye, ogbigbi awo isalu orun. Bi kowe awo aye ba ke awon agbagba aye a ma gba ode orun lo, bi ogbigbi awo isalu orun bake awon omo wewe orun a ma bo wa saye, ese oba akaye, ese oba akaja, ni won sa'agede fun orunmila nigba awon ota rogba yika, ifa ni to ba sebi temi -omo- bani, emi o segun ota, emi o reyin odi, iba se oso/aje/emere etc ni nba sa simi ni, ewe owo ni yio ma wo awon ota mi losorun, eru ni yio ma ru ibi won to won lo, bi igbin ba fa ikarahun re atele, obaraka bami ran awon ota mi lo sorun.

EWE IFA: ewe owo wewe, eru awonka, igbin kan. Ao jo won po pelu igbin na tikarahun re. Ao wa ni ihoho, ao te ebu na ni obara ika ni ilele lori cement lenu ona yara wa, ao pe igede na si,ao ka owo wa seyin lori ikunle, ao la pelu ahon wa. ao ta epo si oju ilele ti ati la ebu na. Ise yi wa fun eni ti o ba ni ota pupo. Ekan losu laoma la.

IBA ELEDUMARE OBA TO BA LORI OUN GBOGBO, IBA RE ORI MI, IBA EYIN AFINJU EYE TI NJE LORU TI IDAGIRI KI DA LONA, IBA GBOGBO AWO TI O WA LORI PAGE YIO. ABORU ABOYE ABOSISE O.

1 Like

Culture / Re: Ogun Awon Bàba Wa by marv006: 1:26am On Feb 21, 2016
ayokomi1010:
OGUN EBE AWON AGBA
obi pupa kan,funfun kan,ewe ata ijosi,ao gun Mo ose ao mawe.
(²) igbin kan,odu ori ewe ahunekun,epo obo,ao gun dada ao fi ose po ao ko sinu aso funfun,wiwe ni odaju

Iba Eyin agba o. Se ao fi aso funfun ti a ko ose ko si oke ni, abi a le fi si ibi to ba wuwa.
Culture / Re: .. by marv006: 12:55pm On Feb 20, 2016
healthFirst:
116

BI AYE BA DE EEYAN MOLE
Odindi Aaye Okete kan, ao gun ninu Odo pelu Ata Ijosi die ati Eepo Obo die pelu Ose dudu. Ao maa we ninu Apere ajadi fun ojo meje pelu omi to lo wooro.

Baba mo ki yin fun ise nla te nse fun wa o, ewe a maje o. Nje ta ba ti se bi eti so, tasi lo bi etiso, se ao ri ayi pada rere. Baba ejowo,e yo nda ise yi fun mi.

1 Like 1 Share

(1) (of 1 pages)

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 49
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.