Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,174,247 members, 7,891,173 topics. Date: Tuesday, 16 July 2024 at 09:28 AM

Oloriireomo's Posts

Nairaland Forum / Oloriireomo's Profile / Oloriireomo's Posts

(1) (of 1 pages)

Literature / Ewí Ìfé by oloriireomo(m): 7:40pm On Jan 07, 2014
"Erékùsù ni mo wà
níìgbàtí atukò ìfé re dé.
ìfé re gbé mi bí àjà.
mo ti kan lu àgbami odò
ìfé re ná,afi kí n yó démúdémú.
irún wu apárí
orò wu òle.
ojú ti elégàn lórí òrò ìfé wa.
mo joyin olá tèmi nìkan.
ojú oró ló lomi
òsíbàtà ló lodò.
saworo ló niìlù, ìlù ló ni saworo.
ìwo lo ni mi,èmi mo ni é.
kòsí ìrì léhìn òjò ìfé wa.
Bí ìgbín bá fà ìkarahun a tèle lòrò ìfé wa.
òtàlénígba eye ló n be nínú igbó,
sùngbón òkín lolórí won.
Nínú gbogbo àwon ògegèlè ti n be laye
ìwo ladédàá fi joba ewà lé won lórí.
..

1 Like

Literature/Writing Ads / Rárà Sísun by oloriireomo(m): 7:21am On Jan 04, 2014
ÀLÀYÉ NÍ SÓKÍ NÍPA "RÁRÀ SÍSUN"
O seni ní kàéfì pé àwon omo yorùbá kan kò
mo nkan ti a n peni ràrà
sísun.
To o....e jé kí
a se àlàyé nípa "Rárà sísun .
Aárìn obìnrin ní rárà sisun ti wópò.kìí se pé
àwon okùnrin náà kìî sun rárà o.sùngbón
àarin àwon obìnrin ló wôpò sí jùlo.
Ibí tí wón ti n sun rárà níyìí,bóyá okúnrin
tàbí obìnrin.
•ìsìnkú àgbà
•ibi ìsílé
• oyé jíje tàbí níbi ìsomo lórúko.
Ìwádìí n lo lówó láti mò bóyá okùnrin tàbí
obìnrin ló sun rárá lójó ìsomo lórúko àwa
Èjìrè.tàbí won ò ti è sun rárà rárá.tí ìwádìí
bá parí a ó ò fi tóyín létí.
"Dùndùn,aro àti sèkèrè ni wón n lù láti ki
Oba,ìjòyè,olówó,olólá,bòròkìní, akoni àti
gbajúmò.
wón fi n ki oríkì-orílè,sòrò àyésí,sòrò
àpónlé tàbí toro èbùn.
Asunrárà gbódò mo ìtàn dáadáa.
E jé kí á wo àpeere yìí:
Àjàdí èsó,
omo oníkòyí
iwájú ni baba yín fí I
gbota,
ìran ìkòyí tó gbofà
léhìn ojo ló se;
Àjàdí bó o lè kóle,
bóo fún mi n ò ní bínú.
YORÙBÁ DÙN!!!!!!!!!!!!!!!! i love it plenty
plenty.
•Omo yoòbá àtàtà.

1 Like

Literature / Ekún Ìyàwó by oloriireomo(m): 10:17am On Jan 03, 2014
EKÚN ÌYÀWÓ.

Ati dá ara lékòó nípa" ràrà sísun "l'órí ètò yìí sáájú àkókò yìí.

Ní òní yìí e jé kí á gbé ohun tí wôn n pèní ekún ìyàwó wò.

Ní ilè yorùbá,ìyàwó titun tí ó ku bí ojó márùn-ún láti losí ilé oko ló n sun ekún ìyàwó káàkiri ilé òbí àti ebí rè láti gba ìre lenu won àti láti dágbére fún won pé 'ìlo tiyá, oníbodè apòmù.

•ìyàwò yóò má a ki oríkì-orílè òbí rè
•ìyàwó yóò má a sòrò nípa ilé oko rè,ìyá oko,bàbá oko tàbí orogún.


E jé kí á wo àpeere yìí:
ìyàwo yóò kúnlè sí iwájú àwon òbí rè tàbí ebí rè,tí ó bá jé iwájú òbí rè yó sì má a wí báyìí pé.

" ilé oko yá,
mo wá gbare è mi
Èmi Àdùké òpómúléró
moja lekàn,
Bàbá tí mo ní
mo dúpé kíké tée ké mi,
ìyà tí moní mo dúpé gígè tèe gèmí.(abbl).

Léyìn náà,ìyá á gbówó lé e léjìká.yó wà súre fún pèlú omijé lójú.

" Àdùké òpómúléró moja lekàn.
ilé oko lo n lo kélédà ìyá mi má a
sìn o lo.ìkó kìí kéjo lésé.ní ilé oko wà á bí
okúnrin àbiro,obìnrin àbíyè...(abbl).


Gbogbo àwon àdúrà yìí ni kìí jé kí omo ó kàgbákò tàbí bá elénìní pàdé n lé oko.wón á boko gbé dojo alé.
sùngbón láyé òde òní nko?gbogbo àwon àsà wònyí tí d'ohun àmúpìtàn.



YORÙBÁ DÙN GBÓNGBÓN!!!! I love it plenty plenty.


•omo yoòbá àtàtá
Literature / Re: Olómo Ló Layé.omo Wa Ò Nì Kú Mó Wa Lójú by oloriireomo(m): 6:06am On Dec 16, 2013
Thank u all
Literature / Olómo Ló Layé.omo Wa Ò Nì Kú Mó Wa Lójú by oloriireomo(m): 5:42am On Nov 25, 2013
""By;olóríire omokótuòjíire èjíwòrò

|}-Olómo ló layé,
Èdùmàrè wá fúnwa lómo àmúsèye.
Omo tíí tójú ará,
Tíí tójú ile,
Tíí tójú òbí,
Fúnwa lómo àtàtà.
Tíí múnú ìyá dùn!
Gbogbo omo tuntun tin be láyé,
Orógbó lóní kéegbo,
Gbó pèlú ìdèra.
Omo owó kìí kú lójú owó, omo esè kìí kú lójú ese
àwon Omo wa ò níkú.
Tiyin naa ò ní dàgbégbín bí èbù isu.
Odoodún la n rórógbó,
Odoodún la n ráwùsá,
Odoodún la n rómo obì lórí àte.
Lodoodún ni lolorun o fomo rere
Ke gbogbo en to nwomo.
Bibi la bimo tunntun,
Èdùmàrè jómo tuntun ò dàgbà
Koun náà ó dolómo láyé.
Kulukulukulu omo weere
Lódèdè gbogbo wa.
Aboyún inu ko bi tibi tire,
A kìí gbèbí ewúré
Akìí gbèbí àgùntán
Lójó ìkúnlè aboyún.
Ká gbóhùn ìyá
Ká gbó tomo titun
Wéré lewé nbó lára igi
Gbèdè níí ro kókò lágbàlá
A taboyun a ti koko!
Yio royin lorun gbedemuke.
Omidan to n woko
Koluwa o funwon lóko rere.
Àpón tí òlaya,
Gbaya rere kowon lona.
Aya eleso.
Ogede kii gbodo ko yagan
Je ki won o fowo bosun ki won fi pamo lara
A tomidan a tapon
Èdùmàrè wa dawon lohun lasiko
Agbe níí gbére pàdé olókun,
Alùkò níí gbére pàdé olósà
Koluwa o gbomo rere pade awa.
Bíná bákú á feérú bojú
Bógèdè bá kú a fomo è rópò.
Ojó táa bá pajúdé
Omo rere ni kó jogú wa .

1 Like

Literature / Ore Ti Ko Common by oloriireomo(m): 12:48pm On Nov 21, 2013
True touching heart story,i must read.
Onkọtan- oloriire ọmọ
Akọle : oore ti ko common


Ọgbẹni kan de si ilu eko lati oke okun.ọmọ bibi ilẹ gombe ni,sungbọn oke okun lo tẹdo si lati ìgbà ewe rẹ,idi nipe ibẹni awọn obi rẹ f'Orí rẹ sọ'lẹ si.
Ko de ilẹ adulawọ ri.

Ni owurọ ọjọ kan o de si ipinlẹ eko,lọwọ awọn ero ti o ko lọna o beere,,' ẹ dakun mo ń wa arakunrin kan ti o dudu diẹ ,ti o ni irungbọn yẹhukẹ,ti o ga diẹ ,ti o ni sasa loju,'rárá o,ako mọ ẹni naa "awọn erona fesi. ko s'ẹni to mọ ẹni to ń sọ ,wọn si ro wipe Orí rẹ ti ń yi diẹ diẹ ni tabi o ti ta ogogoro diẹ sọfun.

Ko pẹ pupọ ti akusẹ ẹlẹmu kan to ń fi kẹkẹ kiri ẹmu ń kọja lọ.arakunrin yii ri ,o sare tọọ lọ ,o sunmọ .tọwọ- tọwọ o wipe"ẹ ma binu sa,ẹyin ni mo wa wa lati oke okun....Ọlọ́runwipe okunrin kan wà ni ilu eko, o dudu diẹ , o ni irungbọn yẹhukẹ,o ga diẹ ,o ni sasa loju ni eyi ti o tumọsi pé ẹ yin ni ẹni naa.mo ti daamu jinna ,lati ijẹta ni moti ń daamu kaa kiri. Ọlọ́run wipe ki ń saanu fun yin.ẹ ma binu pé mo gba akoko yin.ẹ gba sọwedowo yi ,millionu mẹwa ni mo kọ si inú ẹ,ki ẹ gba owo naa ni ile ifowa pamọ banki akọkọ ti o ba sunmọ agbegbe yin.ko tán sibẹ o, ẹgbẹrun lọna aadọta naira niyi ki ẹ fi s'owo apo nitori pé ẹ le ma i tii raaye lọsi ile ifowopamọ.ẹ gba kọkọrọ ọkọ ọlọyẹ ti mo wà gunlẹ si ọọkan yẹn.ẹ dakun ẹ ma binu pé mofi akoko yin sofo,ti mi o ba se nnkan ti mo ń se yi ara koni dẹmi ,'ọgbẹni wi.",kinni ń o fisan -an fun ọ Ọlọ́run mi ,iru oore ń la banta banta ti o se funmi yii?,'ẹlẹ mun wi,osi daku loju ẹsẹ.

Omi garawa mẹwa ni wọn dale ́ lórí koto pada ji saye.loni yii,ọgbẹni ẹlẹmu ti ni ile ni V.i (victoria iland)ni ilu eko.osi ti di ẹni ti ń lọsi oke okun bí ẹni to ń lọsi ọja.
Ni fẹẹrẹfẹ ti o ku ki ọdun yii o kẹru rẹ ń lẹ,mo wure fun ọgbọn ènìyàn ti o ba ri amin kan se tabi fẹran :
•Ni ibikibi ti oloore rẹ wà,ara koni rọ'kun kosi ni rọ adiẹ rẹ afi bo ba se ọ loore.
•Afẹfẹ koni fẹ ko ma kan igi oko lara...ni ibi kibi ti alaanu rẹ ba wà koma wa ọ .boba ń sun ko taji,boba ń rin ko tẹsẹmọrin máa bọ lọdọ rẹ .

•Alaanu rẹ yoo wa ọ ri.

• Loni , ọrun si iwe iranti kan ọ

•Ni aye rẹ,ibanujẹ k'ẹru rẹ .

•Ibanujẹ kẹru rẹ

• Ẹkun oun ose k'ẹru rẹ.

• O ti dagbere fun osi loni.

• O dagbere fun isẹ(poverty).
[b]True touching heart story,i must read.
Onkọtan- oloriire ọmọ
Akọle : oore ti ko common


Ọgbẹni kan de si ilu eko lati oke okun.ọmọ bibi ilẹ gombe ni,sungbọn oke okun lo tẹdo si lati ìgbà ewe rẹ,idi nipe ibẹni awọn obi rẹ f'Orí rẹ sọ'lẹ si.
Ko de ilẹ adulawọ ri.

Ni owurọ ọjọ kan o de si ipinlẹ eko,lọwọ awọn ero ti o ko lọna o beere,,' ẹ dakun mo ń wa arakunrin kan ti o dudu diẹ ,ti o ni irungbọn yẹhukẹ,ti o ga diẹ ,ti o ni sasa loju,'rárá o,ako mọ ẹni naa "awọn erona fesi. ko s'ẹni to mọ ẹni to ń sọ ,wọn si ro wipe Orí rẹ ti ń yi diẹ diẹ ni tabi o ti ta ogogoro diẹ sọfun.

Ko pẹ pupọ ti akusẹ ẹlẹmu kan to ń fi kẹkẹ kiri ẹmu ń kọja lọ.arakunrin yii ri ,o sare tọọ lọ ,o sunmọ .tọwọ- tọwọ o wipe"ẹ ma binu sa,ẹyin ni mo wa wa lati oke okun....Ọlọ́runwipe okunrin kan wà ni ilu eko, o dudu diẹ , o ni irungbọn yẹhukẹ,o ga diẹ ,o ni sasa loju ni eyi ti o tumọsi pé ẹ yin ni ẹni naa.mo ti daamu jinna ,lati ijẹta ni moti ń daamu kaa kiri. Ọlọ́run wipe ki ń saanu fun yin.ẹ ma binu pé mo gba akoko yin.ẹ gba sọwedowo yi ,millionu mẹwa ni mo kọ si inú ẹ,ki ẹ gba owo naa ni ile ifowa pamọ banki akọkọ ti o ba sunmọ agbegbe yin.ko tán sibẹ o, ẹgbẹrun lọna aadọta naira niyi ki ẹ fi s'owo apo nitori pé ẹ le ma i tii raaye lọsi ile ifowopamọ.ẹ gba kọkọrọ ọkọ ọlọyẹ ti mo wà gunlẹ si ọọkan yẹn.ẹ dakun ẹ ma binu pé mofi akoko yin sofo,ti mi o ba se nnkan ti mo ń se yi ara koni dẹmi ,'ọgbẹni wi.",kinni ń o fisan -an fun ọ Ọlọ́run mi ,iru oore ń la banta banta ti o se funmi yii?,'ẹlẹ mun wi,osi daku loju ẹsẹ.

Omi garawa mẹwa ni wọn dale ́ lórí koto pada ji saye.loni yii,ọgbẹni ẹlẹmu ti ni ile ni V.i (victoria iland)ni ilu eko.osi ti di ẹni ti ń lọsi oke okun bí ẹni to ń lọsi ọja.
Ni fẹẹrẹfẹ ti o ku ki ọdun yii o kẹru rẹ ń lẹ,mo wure fun ọgbọn ènìyàn ti o ba ri amin kan se tabi fẹran :
•Ni ibikibi ti oloore rẹ wà,ara koni rọ'kun kosi ni rọ adiẹ rẹ afi bo ba se ọ loore.
•Afẹfẹ koni fẹ ko ma kan igi oko lara...ni ibi kibi ti alaanu rẹ ba wà koma wa ọ .boba ń sun ko taji,boba ń rin ko tẹsẹmọrin máa bọ lọdọ rẹ .

•Alaanu rẹ yoo wa ọ ri.

• Loni , ọrun si iwe iranti kan ọ

•Ni aye rẹ,ibanujẹ k'ẹru rẹ .

•Ibanujẹ kẹru rẹ

• Ẹkun oun ose k'ẹru rẹ.

• O ti dagbere fun osi loni.

• O dagbere fun isẹ(poverty).
[/b]True touching heart story,i must read.
Onkọtan- oloriire ọmọ
Akọle : oore ti ko common


Ọgbẹni kan de si ilu eko lati oke okun.ọmọ bibi ilẹ gombe ni,sungbọn oke okun lo tẹdo si lati ìgbà ewe rẹ,idi nipe ibẹni awọn obi rẹ f'Orí rẹ sọ'lẹ si.
Ko de ilẹ adulawọ ri.

Ni owurọ ọjọ kan o de si ipinlẹ eko,lọwọ awọn ero ti o ko lọna o beere,,' ẹ dakun mo ń wa arakunrin kan ti o dudu diẹ ,ti o ni irungbọn yẹhukẹ,ti o ga diẹ ,ti o ni sasa loju,'rárá o,ako mọ ẹni naa "awọn erona fesi. ko s'ẹni to mọ ẹni to ń sọ ,wọn si ro wipe Orí rẹ ti ń yi diẹ diẹ ni tabi o ti ta ogogoro diẹ sọfun.

Ko pẹ pupọ ti akusẹ ẹlẹmu kan to ń fi kẹkẹ kiri ẹmu ń kọja lọ.arakunrin yii ri ,o sare tọọ lọ ,o sunmọ .tọwọ- tọwọ o wipe"ẹ ma binu sa,ẹyin ni mo wa wa lati oke okun....Ọlọ́runwipe okunrin kan wà ni ilu eko, o dudu diẹ , o ni irungbọn yẹhukẹ,o ga diẹ ,o ni sasa loju ni eyi ti o tumọsi pé ẹ yin ni ẹni naa.mo ti daamu jinna ,lati ijẹta ni moti ń daamu kaa kiri. Ọlọ́run wipe ki ń saanu fun yin.ẹ ma binu pé mo gba akoko yin.ẹ gba sọwedowo yi ,millionu mẹwa ni mo kọ si inú ẹ,ki ẹ gba owo naa ni ile ifowa pamọ banki akọkọ ti o ba sunmọ agbegbe yin.ko tán sibẹ o, ẹgbẹrun lọna aadọta naira niyi ki ẹ fi s'owo apo nitori pé ẹ le ma i tii raaye lọsi ile ifowopamọ.ẹ gba kọkọrọ ọkọ ọlọyẹ ti mo wà gunlẹ si ọọkan yẹn.ẹ dakun ẹ ma binu pé mofi akoko yin sofo,ti mi o ba se nnkan ti mo ń se yi ara koni dẹmi ,'ọgbẹni wi.",kinni ń o fisan -an fun ọ Ọlọ́run mi ,iru oore ń la banta banta ti o se funmi yii?,'ẹlẹ mun wi,osi daku loju ẹsẹ.

Omi garawa mẹwa ni wọn dale ́ lórí koto pada ji saye.loni yii,ọgbẹni ẹlẹmu ti ni ile ni V.i (victoria iland)ni ilu eko.osi ti di ẹni ti ń lọsi oke okun bí ẹni to ń lọsi ọja.
Ni fẹẹrẹfẹ ti o ku ki ọdun yii o kẹru rẹ ń lẹ,mo wure fun ọgbọn ènìyàn ti o ba ri amin kan se tabi fẹran :
•Ni ibikibi ti oloore rẹ wà,ara koni rọ'kun kosi ni rọ adiẹ rẹ afi bo ba se ọ loore.
•Afẹfẹ koni fẹ ko ma kan igi oko lara...ni ibi kibi ti alaanu rẹ ba wà koma wa ọ .boba ń sun ko taji,boba ń rin ko tẹsẹmọrin máa bọ lọdọ rẹ .

•Alaanu rẹ yoo wa ọ ri.

• Loni , ọrun si iwe iranti kan ọ

•Ni aye rẹ,ibanujẹ k'ẹru rẹ .

•Ibanujẹ kẹru rẹ

• Ẹkun oun ose k'ẹru rẹ.

• O ti dagbere fun osi loni.

• O dagbere fun isẹ(poverty).
Literature / Orin Orile Ede Naijiria Ni Ede Yoruba Ati Ni Geesi by oloriireomo(m): 2:28pm On Sep 25, 2013
Anthem in Yoruba

"Dide eyin ara Wa jepe Naijiria, ka fife sinlee wa,
pelokun atigbagbo,
kise awon akoni wa,
ko ma se ja sasan,
ka sin tokan~tara,
Ile tominira,
alaafia so dokan.
.

O God of creation(olorun eleda wa)


Olorun Eledaa;
To ipa ona wa;
Fona han asaaju,
Kodoo wa motito;
Kododo atife po si i,
Kaye won je pipe;
So won deni giga;
Kalaafia oun eto
Le joba nile wa

The pledge in yoruba:


Mo se ileri fun orile ede Nageria,
lati je olododo, ati eniti o se fokan-tan,
Lati sin pelu gbogbo agbara mi, ati lati gbe ga fun iyin ati ogo re.
Ki Olorun ki o ran-mi lowo (Amin)
Ise olorun ni.
...............................................................................................
...............................................................................................
Anthem in ENGLISH:

Arise ,o compatriots Nigeria's call obey
To serve our fatherland with love and strength and faith the labour of our heroes past shall never be in vain.
To serve with heart and might one nation bound in freedom,peace and unity .

•National pledge:

I pledge to Nigeria my country,
To be faithful, loyal and honest,
To serve Nigeria with all my strength,
To defend her unity,
And uphold her honor and glory,
So help me God.
........................................................................

2 Likes 1 Share

Literature / Re: Itan Sebi Otimo by oloriireomo(m): 10:04am On Sep 12, 2013
Amin
Literature / Itan Alajo Somolu by oloriireomo(m): 6:07pm On Sep 11, 2013
Alajo Somolu

Bi a bá r'enikan t'o ja fafa, a maa nso pé ori e pé bi ori baba Alájo Shomolu to ta mótò ra keke, to gba ajo l’owo eédégbeta eniyan láì wo ìwé, o da owo onikaluku pada láì si owó san f’enikankan.

Ta a ni Alajo Somolu gan?
Sàsà ènìyàn ló mò pé, èèyàn gidi ni Alajo Somolu ti won maa ns’òrò è yi, kii se eni inu ìtàn aroso rara.

Ni odun 1915, ni Isonyin Ijebu, obinrin kan bi ibeta ni asiko to jé pe nkan ìbèrù ati kàyéfì ni ki eeyan bi ju omo kan lo.
Nitori àsà ìgbàanì, ààyè ni won sin Etaòkò, won fi se ètùtù ki awon alálè o lè f’iyedénú. Ko pé si asiko yi naa ti Kehinde lo ra aso wa, o ku Taiwo nikan s’áyé.

Oju Taiwo ri èélááfí. Odomode ló wà ti baba rè fi s’ílè bora bi aso. Nigba ti kò si ònà lati ka iwe jinna, Taiwofi Isonyin Ijebu silè, o wa ise aje lo si Eko Akete. O fi ara rè si èkósé aránso nigba tó de Eko.

Taiwo kósé ó mo’sé, kó ná ìná àpà ó ra okò akérò. Laipe, o fi okò wiwà silè ó bèrè esúsú tabi ajo ojúmó. Taiwo ta oko akero yi, o ra kèké ológeere nitori kèké lo lè maa gbe lo si gbogbo ibi ti awon olójà to nsan esúsú wà.
Ki ni Taiwo rò de ibi ajo gbigba? Awon ile ifowopamo to wa l’asiko yi ò ri ti awon iyalójà ati babalójà gbó, awon ile ise nla nla ni onibaràwon.

Taiwo bere sii gba èsuntéré owó ajo ojumo l’owo awon mekúnnù olójà, o nko fun won kìtí n’íparí osù. O nyá won l’owo lai gba dukia kankan fun iduro.
Bi eré bi eré, òkòwò èsúsú yi ngbilè, béè ni ojà awon onibara rè naa ngbèrú si. Taiwo di ayànfé gbogbo olójà, o di ìlúmòká alájo ojúmó. Ibi ti ounti a mò si Ile ifowopamo Mekunnu l’oni ti bere ni yen.
"Awon agbègbè tó jé àrésèpa fun Taiwo ni Sangross, Baba Olóòsà, Ojúwòyè, Awolowo, Oyingbo, Olaleye ati Shomolu,gbogbo oja ati agbègbè ti a daruko yi ni Taiwo ti ngba àjo. Awon onibara re feran rewon si f’inu tan tori won ò ri ki Taiwo ó fi dúdú pe funfun fun won.
Alakori kii s’egbe alakowe nigba naa. Ko si erò isirò ti a mo si calculator, sugbon ori Taiwo pé, o ns’isé bi aago ni. Láì wo iwe akosílè, Taiwo a má a so iye ti enikookan ti dá si òun lówó.

Bi enikeni sì ba Taiwo jiyan, nigba ti won ba jo gbé gègé le isiro, won a gba fun Taiwo kehin naa ni tori bo bá se wi pe o ri naa ni won ó ba a.

Gbogbo awon onibara rè ló féki omo won o ni ori pipe bii Taiwo, won a si maa fi se akawe pe, ‘Ori omo mi pe bi ti Baba Alajo Somolu”,
Itan baba Alajo Somolu yi fi han wa bi aye se dara to ni asiko yen, kò si jìbìtì.

Se awon eniyan kó ni won da ile ifowopamo sile ti won so ara won di eku òfónòn si wa l’orun, awon èèkàn inu ijo Olorun ti Oniwaasu nwárí fun? Taiwo fi igboya, oyaya, ati otito inu se ise re lai ri awokose kankan, ó si di eekan pataki ninu itan ile Yoruba ti a nfi oruko rè suref’omo eni.
Ninu ikoko dudu l’eko funfun ti njade.
Baba Alajo Somolu wo sakun òrò, o woye nkan ti awon arailu nilò, lai ri iranlowo ijoba tabi ti olówó kan, o pakiti mole, pelu ifojúsùn ati èrò peatelewo eni kii tan’ni í je, o tiipa béè gba aimoye idile l’ówóebi ati ìsé, o gba mekúnnù l’owo awon agbàlówóméèrí ileifowópamo, ó ti ipa béè di olokiki eniyan titi ti oro re fi di àsà ti a ndá.

Taiwo Olunaike fi oruko to dara silè de omo ati àrómodómo rè. Titi ayé, ti àsà ati èdè Yoruba ba si nwà, a ò ni yé so fun eni ti ori è pé wipé “Ori è pe bi ori Alajo Somolu”. Oruko wo ni iwo fé fi silè de awon iran tó nbò l’éyìn? Se eèkàn ni o ninu isekuse, àjààgbilà, isokúso, iwa olè, kenimání, jandùkú, ati gbogbo iwà buruku ayé? Ki tie ni èkó ti iwo nkó omo re? Ki ni aládúgbò nwi nipa re?
Tulétúlé ni o abi Atúnlútò? Oba to je ti ilú tòrò ati eyi to je ti ilú dàrú, oruko won ò ni jo pare ni, sugbon ki ni a ó so nipa ti iwo?
Nje kò ye ki a kó ogbón nla ninu itan Taiwo Olunaike yi paapaa ni asikò ti isé wón bi imí eégún ni orile èdè Naijiria, ti awon omo wa ti m’órí lé òkè òkun tán. Ohun tielòmíìn nwa lo si sokoto nbe ni apo sokoto re.
Awon olójà ò kuku ke gbàjarè lo s’ilé oba béè ni won ò ké gbàmí gbàmí to Taiwo Olunaike, sugbon òun de oju silè, o fi riimu. Làákàyè ti Taiwo Olunaike lò kii se eyi ti a kó oni ilé ìwé, ogbón inú l’ejò fi ng’àgbon. Njé ìwo ò ma f’oju témbélú orisirisi ànfààni to wa ni igi imu re nitori ìgberaga ati ìwà òle? Ki ni o lè se lati ran ilú tabi adúgbò re l’ówó?

1 Like

Literature / Re: Itan Akonilogbon by oloriireomo(m): 6:03pm On Sep 11, 2013
E seun lae.b'oro ile aye se ri nun-un
Literature / Itan Sebi Otimo by oloriireomo(m): 5:54pm On Sep 11, 2013
SE BI O TI MO, ELEWA SAPON,OWE NI TABI OWE KO?KA ITAN YI

Idalasa yii kiise owe tabi asayan rara.
,iya kan nii dasa be laye igbakan .

asa yii ti di ka'leka'ko ni ilẹ Yoruba titi d'oni yii.

Oja kan wa ni Abeokuta ni ipinle Ogun,o gbayi pupo laiye atijo, oja naa ni gbogbo awon ti ko laya n'le tabi apon ti ma n fatapase(jeun) ajeyo si ni won ma n je. idi rè niyen ti won fi npe ọja naa ni Saponloore.

Oja Sapọn ni iya kan ti oruko re nje Odesola ti nta ewa sise, oun naa lo si maa n daasa Sebootimo.

Ewa iya yi dun to beege to fi jẹ pe kia lo gb’ori l’owo gbogbo awon ẹlẹwa yooju ni agbegbe re.

Ikoko ẹwa jabete kan lo fi bẹrẹ owo yii sugbon ko pẹ pupọ ti isẹ yi fi kuro ni keremi, o deni tii se odindi apo ẹwa kan tan l’ọjọ kan soso.

Ikoko ẹwa a wa lo bii rẹrẹ ni isọ re pẹlu ogunlọgọ awon ọmọ isẹ. Se ni ọgọọrọ ero a pe le lori pitimu,biigba teegun ba n jo tero sii n woran. ti won a to lọ bẹẹrẹ lati ra ẹwa, afi bii pe o se awure .

Bi awon kan ti nj’oko jẹ ẹ ni isọ rẹ l’awon miin a ra a lọ s’ile won.
Ninu ita arigbo pe, eja n’iya yi nta niigba kan ri. Eja panla lo n kiri lọ l’ọjọ kan ló ni k’oun ra ẹwa jẹ l’adugbo kan ni Abeokuta. Obẹ ata ti won bù lé ori ewa fún un buru jai kosi te l’ọrun idi niyi ti oun naa fi pinnu lati bẹrẹ ẹwa tita.ose atunse si ewa tie ki oun naa ma baa se iru asise eyi ti elewa ibi ti oti ra se.

Agbo ninu itan pe iya yii ka iwe mefa aye igba naa,iyen Standard 6.

Asa sebootimọ yi lo maa nda nigba ti owo ẹwa re yi bureke tan.

O ma n sofun awon onibara re pe ki won sebi wonti mo(sebootimo), ki won ma je ju iwon owo to wa l’apo wọn lọ, ki wọn ma si ra ẹwa ju iwọn ti ikun wọn le gba lọ bi won ti e jeun sapo daadaa.

Otun ma n dasa yii k'ewa re ma baa tete tan .

Niigba mii t'ewa ba ti tan ti awon kan ba beere pe kilode ti ko se ewa si a ni ‘'n o le se ju agbara mi lo, se bo o ti mo l’aye gba’.

Iya elewa sopon yii siwa lori eepe titi doni yii.sungbon agba tide,kosi le sa kijo kijo kiri bii tatehinwa mo.
Ko ta ewa mo,ara n fe isinmi fakafiki lojoojumo.orin baba wa kan nun-un.

odun marunlelogoji ni iya yii fi tewa koto sinmi sile(retire)ni odun 1996.

Ninu itan,a gbo pe iya yii ti ta ewa fun oba ilu kan ri.koda ni aimoye igba ti oba yii bani awon alejo nla jankan-jankan ti ti wonsi nipe ewa lowun awon,iya yii ni won o gbe kontirati yi fun.

Kinnikan lowa yani lenu o.

Ni bayi,iya yii ti di ayalegbe, koda ati san'wo ile ti d'ogundode.kama wule menu ba oro ounje rara.Ipo ti iya yii wa bayi yato si aye igbaani.niigba ti ara se kosakosa.

O dami loju pe e o gbagbe itan baba alajo somolu?ara awon eniire niyen.itan iya alajo elewa saponloore niyi o.a o le gbagbe awon eniire mo ,oniirese ti fingba bi won o fingba mo eyi ti wonfi kole pare mo laelae. B'aye gbagbe ijoye tabi gbagbe olowo won o le gbagbe awon eni ire wonyi niiwon igba ti ina ede Yoruba ba ti n jo geerege.oun re o.

Kinni ipa tire ninu igbelaruge asa ati ede yoruba?

Kinni ise takuntakun re lati je o se'ranti re boo ba lo laye?


Hun!amo a o ni tori awijare kiito otan lenu.

A n gbadura pe k'oba adaniwaye o b'oju aanu wo iya elewa sapon lati aye dorun,ko boju aanu wo emi ejiworo,ebi mi,ati eyin ore mi lapapo.
Literature / Re: Itan Akonilogbon by oloriireomo(m): 3:33pm On Sep 11, 2013
Alright
Literature / Ore Odaju by oloriireomo(m): 3:24pm On Sep 11, 2013
ORE ODAJU

"Olorun yoo pese Jiipu fun o,sungbon koni fimi se dereba re.
Ase looto ni wipe bi iya nla ba gbe'ni sanle kekere asi tun gori eni.
Ore timo timo ni Olatide ati Ayo ola lati igba ewe wa.

Ile iwe kan naa ni awon mejeeji lo.yooba bo won wipe ogun omode ko le sere f'ogun odun.
Leyin ti olatide ati ayoola ti pari iwe mefa ni egbon iya ayoola ti mu ayoola kuro labule losi abuja.aso ni egbon iya re yi n ta .odo re naa ni ayoola ngbe.

"Olatide je oniwa irele,osi je olooto si ore re ayoola.kii fi asiri kankan pamo fun.koda bi wonba bun-un ni tooro yoo sofun ayoola ore re yoosi fun ni eto tire naa.egan lotun ku,ore daada ni olatide.

Leyin ti ayoola ti kuro labule,olatide ko gboro ore re mo,opo igba ni olatide ma n wa ekun mun bii gaari ijebu ni akoko ti aaro ore re ayoola ba n so.niigbami ewe,bii koma danikan soro tabi ko ma sebi alaaganaa. kii jeun,afi ekun saa.kole se deede mo lenu eko re bii ti ateyin wa.
Igba ko lo bi orere ojo ko to o lo bi opa iban.
leyin ti olatide ti pari iwe mefa loti sinmi.idi si ni pe koni oluran lowo,awon obiire sini yii aje ko bawon d'ore rara.oko agbaro ni olatide nse labule...o tun ma n ba awon oni biriki pon omi kobo tabi ko se'gi ta.humm!aa sa buta.

Ni irole ojokan,idi ayo olopon ni olatide ati awon elegbe re wa,ti oko ayokele mesidiisi bobinni kan gunle,awon okunrin gende to san-angun merin sare jade ninu oko,won sare siilekun oko. ayoola sokole ninu oko ninu ola-n-la,o f'owo geresi aso re daada.agbada lo wo lojo naa.ikan lara awon gende merin to tele sare gba potifolio owo re.
Tani mo n woyi ?lo jade lenu Olatide.o f'owo bo'ju e daada boya oju oun n ri dobu.Olatide f'ayo pade ore re,o dimo....ayo kun inu re,erin si pa eke re.
Olatide mun Ore re losi ibugbe re.nigba ti wonde ibugbe re,awon ibeere gbankogbi t'ole yo ile aye lemi eeyan lo n jade lenu ayoola.
Ayoola:se ibi to n gbe niyi?
Olatide:beeni o,koda mo sese kun-un loda ni.ayoola wole bee lo n wo yan-an-yan-yan bi eni tofe d'oogun le,o f'owo bo'mu....,olatide fi yara re han.ibeere mii lotun beere"
Ayoola:se yara to n sun naa lori bi yara eku yii?iya ma n je iwo iwo arakunrin yii gan
Olatide:hun!iwolo n wo bee,okele gbigbe pelu ifokanbale............mo dupe emi ati ilera pipe ti olorun funmi.

Ni gbogbo akoko yii Olatide ti n s'akiesi asesa ore re,inu re siti n baje.okan re gb'ogbe,omije gbigbona bo loju re.Ayoola Gbowo le lejika,o tuu pe koma ba okunrin je,osi se ileri lati ran-an-lowo.o sofun Olatide pe oun yoo fisi aaye kan niibi se oun ti yoosi ma gba owo osu niipari osu.o fun ni kaadi ile ise re nii eyi ti adiresi re wa ninu re,pe kowa ri oun ni ile ise oun kosi nii lokan lati bere ise lojo kan naa.inu Olatide dun debi pe bi wonba g'esin ninu re koni ko'se.Ayoola seju si arakunrin t'ogbe potifolio dani,kia,iyen naa timo nkan ti ayoola n fe.o gbe bondu owo kan jade.egberun naira ni won we papo.Ayoola fa eyo egberun kan yoo ninu owo naa o naa si Olatide.olatidegba,inu olatide dun de'badi.o jowo loti gb'orun owo mo.ayoola dagbere osi pada si abuja.
Leyin ojo keta,Olatide gbera odi abuja.ko se wahala jina lojo naa.enu ona ile ise Ayoola gangan ni oko jasi.o wole,o si loore ofe lati ba ayoola niibise lojona.se awon oni bisinesi kii ku duro s'oju kan.amerika loni,katangua ni lola.
Ayoola n ki ore re.

Ayoola:pele o arakunrin

Olatidesadtiyan-tiyanu)o o!

Ayoola:se e mo oko wa daada?

Olatide:Oko?

Ayoola:beeni,oko!

Olatide:mo mo oko wa

Ayoola:yooto bi odun melo ti eti n wa oko bo?ati pe iru awon oko wo ni eti ni ore ofe lati wa?manua tabi otomatiiki?
Olatide:mo mo oko wa daada kosi si eyi ti n ko lewa.bose ajagbe,jagi tabi tipa deede ara lose

Ayoola:inu mi dun bii bi eti dami lohun.a o bere pelu egberun mewa funyin.leyin odun kan,ti aba ri bi eti se daada si alekun yoo ba owo osu yin.

Olatide:E se!oko wo lefe kin wa?ati pe ile ise wo ni mofe wa?

Ayoola:Mo sese fera oko jiipu kan ni,iwo sini mofe koo mo wami niile ise yii.
Olatidesadoun sunkun)e mi naa?biiya n la ba gbeni sanle keke re asi tun g'ori eni.ayoola agh!iwo.laduru bi moti feran re to.o se o,mo dupe pupo.Olorun yoo pese jiipu fun o,amo koni fimi se dereba re.(Olatide sunkun bosita osi n wa oko lati pada s'abule)ibi ti oti n se eyi.....oko ayokele kan gba,oko yii si salo.won gbe Olatide digbadigba lati doola emi re, odi ile iwosan,sungbon ki wonto de'le iwosan. "Olatide Ku"
Literature / Oriki Orile by oloriireomo(m): 3:09pm On Sep 11, 2013
IKOYI ESO


Aporogunjo ikoyi gbera n le o dide ogun to lo,
Ojo kinni to nikoyi ku, oju mi paa lose agba ni mi Ko tii da,sugbon mo kuro lomo agbekorun lo inu oko.
Won gbele won bo onikoyi mo nipekun orisanla,agbedegbede onikoyi lo sun ibe,Atari onikoyi Ko sun ibe, eyin lomo asiju apo piri dagba ofa sofun,pofun yoo yo dagba ofa sile,omo aku fepo tele koto,omo igunnugun bale won a jori akalamagbo bale won a jedo

1 Like

Literature / Re: Itan Akonilogbon by oloriireomo(m): 2:44pm On Sep 11, 2013
Mynd_44:
I am on the road
alright!!
Literature / Re: Itan Akonilogbon by oloriireomo(m): 1:23pm On Sep 11, 2013
How?u dnt get it right?
Literature / Itan Akonilogbon by oloriireomo(m): 1:17pm On Sep 11, 2013
Olorire Omokotuojiire Ejiworo
ODAJU OBINRIN

Gbogbo sanmori tin woko ati eyi ti n waya e dakun e naa suuru si o.a o ni bo s'owo eletan o.
Ife ti akinkunmi ni si omoladun ko lafi we rara.oun se'ke atiige re sungbon isesi omoladun si akinkunmi buru jai.
Lako-labo won loni ise gidi lowo wonsi ri ipo to joju dimu n'ibise won.
Banki ni toko-taya won ti n sise,oko n sise ni fedeliti banki niigbati aya n sise ni oseniiki.
Sungbon kinni kan loba ajao awon ololufe yii je,e o bimi pe kinni?ani apa re gunju'tan lo.la todun ti wonti so yigi igbeyawo, omoladun ko royun ni,ko loyun aaro d'ale ri.sibe-sibe e o lemo ohun ti won n la koja idinipe won kii je ki eti meji bawon gbo ohun tin lo laarin won.won kii ba arawon ja nitori airomobi,akinkunmi gbagbo pe olorun nii s'omo osi daju pe yoo se tawon naa t'asiko bato.
Isele kan sele looro ojo isinmi kan,awon omo ipeere meta kan wa bawon lalejo.awon omo yii jo omoladun bi imumu afi bi eni pe omoladun se "ho,tosi powan sile ni.egan ni he,won jo omoladun -un po.
ara n fu akinkunmi si iyawo re boya oun loti bi awon omo yii si'bikan kawon o to pade .o beere lowo re sungbon o je koye pe kosi nkan to jobe ati pe awon omo aburo oun ni won.
Leyin isele yi,akinkunmi se iwadi siwaju-ati siwaju si.eyin oreyin o r'okodoro oro pe omoladun ti ni oko nii gbakan ri. Wonsi ni awon omo meta.ki oko re to re'wale asa ni won ti feto s'omo bibi leyin omo meta.leyin ti oko re ku ni awon ebi oko re gbogun ti,koto dipe won gbemi re lofi keru jade ti osi fiile okore sile.o ko awon omo re meta naa lo sodo awon alabojuto.leyinnaa lowa bere igbe aye otun koto wa s'alaba pade akinkunmi.akinkunmi to sese bere igbese aye re lotun.niigba ti akinkunmi dele,o gbinaje.ofi ibinu da eru omoladun bagbo.o tito odun meedogun gbako ti wonti so yigi ti kosi somo laarin won.omoladun kosi jewo pe oun ti feto somo bibi tabi jewo pe oun ti lomo siibi kan tele ri.e o roju aye bi??
Wewa n sele ni juniyan.ana ni a gbo nipa seniyan seranko.e dakun se ara ko fu yin si omoladun bayi?se kii se eranko?bii kii se eranko,iwa eranko towu yi n ko?akosi bero.
Kinni oro iyanju ti e nifun akinkunmi?
Eledua yoo mo saa nu fun wa o

(1) (of 1 pages)

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 86
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.